Job 6 YCE

1 JOBU si dahùn o si wipe,

2 A! a ba le iwọ̀n ibinujẹ mi ninu òṣuwọn, ki a si le igbe ọ̀fọ mi le ori òṣuwọn ṣọkan pọ̀!

3 Njẹ nisisiyi, iba wuwo jù iyanrin okun lọ: nitorina li ọ̀rọ mi ṣe ntàse.

4 Nitoripe ọfa Olodumare wọ̀ mi ninu, oró eyiti ọkàn mi mu; ipaiya-ẹ̀ru Ọlorun dotì mi.

5 Kẹtẹkẹtẹ ìgbẹ a ma dún, nigbati o ba ni koriko, tabi ọdá-malu a ma dún sori ijẹ rẹ̀?

6 A le jẹ ohun ti kò li adùn li aini iyọ̀, tabi adùn wà ninu funfun ẹyin?

7 Ohun ti ọkàn mi kọ̀ lati tọ́, on li o dàbi onjẹ mi ti kò ni adùn.

8 A! emi iba lè ri iberè mi gbà; ati pe, ki Ọlọrun le fi ohun ti emi ṣafẹri fun mi.

9 Ani, Ọlọrun iba jẹ pa mi run, ti on iba jẹ ṣiwọ rẹ̀ ki o si ké mi kuro.

10 Nigbana ni emi iba ni itunú sibẹ, ani emi iba mu ọkàn mi le ninu ibinujẹ mi ti kò da ni si: nitori emi kò fi ọ̀rọ Ẹni Mimọ́ nì sin ri.

11 Kili agbara mi ti emi o fi dabá? ki si li opin mi ti emi o fi fà ẹmi mi gùn?

12 Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ?

13 Iranlọwọ mi kò ha wà ninu mi: ọgbọn ha ti salọ kuro lọdọ mi bi?

14 Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀.

15 Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ.

16 Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si.

17 Nigbakũgba ti nwọn ba gboná, nwọn a si yọ́ ṣanlọ, nigbati õrùn ba mú, nwọn si gbẹ kurò ni ipò wọn.

18 Iya ọ̀na wọn a si yipada sapakan, nwọn goke si ibi asan, nwọn si run.

19 Ẹgbẹ ogun Tema nwoye, awọn ọwọ́-èro Seba duro de wọn.

20 Nwọn dãmu, nitoriti nwọn ni abá; nwọn debẹ̀, nwọn si dãmu.

21 Njẹ nisisiyi, ẹnyin dabi wọn; ẹnyin ri irẹ̀silẹ mi, aiya si fò nyin.

22 Emi ha wipe, ẹ mu ohun fun mi wá, tabi pe, ẹ bun mi ni ẹ̀bun ninu ohun ini nyin?

23 Tabi, ẹ gbà mi li ọwọ ọ̀ta nì, tabi, ẹ rà mi padà kuro lọwọ alagbara nì!

24 Ẹ kọ́ mi, emi o si pa ẹnu mi mọ́; ki ẹ si mu mi moye ibiti mo gbe ti ṣìna.

25 Wo! bi ọ̀rọ otitọ ti li agbara to! ṣugbọn kini aròye ibawi nyin jasi?

26 Ẹnyin ṣebi ẹ o ba ọ̀rọ ati ohùn ẹnu ẹniti o taku wi, ti o dabi afẹfẹ.

27 Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin.

28 Nitorina ki eyi ki o tó fun nyin: ẹ ma wò mi! nitoripe o hàn gbangba pe: li oju nyin ni emi kì yio ṣeke.

29 Emi bẹ̀ nyin, ẹ pada, ki o má ṣe jasi ẹ̀ṣẹ: ani ẹ si tun pada, are mi mbẹ ninu ọ̀ran yi.

30 Aiṣedede ha wà li ahọn mi? njẹ itọwò ẹnu mi kò kuku le imọ̀ ohun ti o burujù?