Job 30 YCE

1 ṢUGBỌN nisisiyi awọn ti mo gbà li aburo nfi mi ṣẹ̀sin, baba ẹniti emi kẹgàn lati tò pẹlu awọn ajá agbo-ẹran mi.

2 Pẹlupẹlu agbara ọwọ wọn kini o le igbè fun mi, awọn ẹniti kikún ọjọ wọn kò si.

3 Nitori aini ati ìyan nwọn di ẹni itakete, nwọn si girijẹ ohun jijẹ iju, ti o wà ni isọdahoro ati òfo lati lailai.

4 Awọn ẹniti njá ewe-iyọ li ẹ̀ba igbẹ, gbongbo igikigi li ohun jijẹ wọn.

5 A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè.

6 Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta.

7 Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli.

8 Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.

9 Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn.

10 Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju.

11 Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi.

12 Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi.

13 Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ;

14 Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi.

15 Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma.

16 Ati nisisiyi ọkàn mi si dà jade si mi, ọjọ ipọnju dì mi mu.

17 Oru gùn mi ninu egungun mi, eyiti o bù mi jẹ kò si simi.

18 Nipa agbara nla aṣọ mi di pipada, o si lẹmọ́ mi li ara yika bi ọrùn aṣọ ileke mi.

19 O ti mu mi lọ sinu ẹrẹ̀, emi si dabi ekuru ati ẽru,

20 Emi kepè ọ, iwọ kò si gbọ́ ti emi, emi dide duro, iwọ si fi oju lile wò mi.

21 Iwọ pada di ẹni-ìka si mi, ọwọ agbara rẹ ni iwọ fi de ara rẹ li ọ̀na si mi.

22 Iwọ gbe mi soke si ẹ̀fufu, iwọ mu mi fò lọ, bẹ̃ni iwọ si sọ mi di asan patapata.

23 Emi sa mọ̀ pe iwọ o mu mi lọ sinu ikú, ati si ile-apejọ fun gbogbo alãye.

24 Bi o ti wu ki o ṣe, ẹnikan kì yio ha nawọ rẹ̀ ni igba iṣubu rẹ̀, tabi kì yio ké ninu iparun rẹ̀.

25 Emi kò ha sọkun bi fun ẹniti o wà ninu iṣẹ, ọkàn mi kò ha bajẹ fun talaka bi?

26 Nigbati mo fojusọna fun alafia, ibi si de, nigbati emi duro de imọlẹ, òkunkun si de.

27 Ikùn mi nru, kò si simi, ọjọ ipọnju ti bá mi.

28 Emi nṣọ̀fọ lọ rinkiri laisi õrùn, emi dide duro ni awujọ, mo si kigbe.

29 Emi jasi arakunrin ajáko, emi di ẹgbẹ́ awọn abo-ogongo.

30 Àwọ mi di dudu li ara mi, egungun mi si jórun fun õru.

31 Dùru mi pẹlu si di ti ọ̀fọ, ati ohun-ọnà orin mi si di ohùn awọn ti nsọkún.