1 JOBU si dahùn o si wipe,
2 Kò si ani-ani nibẹ̀, ṣugbọn ẹnyin li awọn enia na, ọgbọ́n yio si kú pẹlu nyin.
3 Ṣugbọn emi ni iyè ninu gẹgẹ bi ẹnyin: emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin: ani, tani kò mọ̀ nkan bi iru wọnyi?
4 Emi dabi ẹniti a nfi ṣe ẹlẹya lọdọ aladugbo rẹ̀, ti o kepe Ọlọrun, ti o si da a lohùn: a nfi olõtọ ẹni-iduro-ṣinṣin rẹrin ẹlẹyà.
5 Ẹgan ni ẹni-òtoṣi, ti ẹsẹ rẹ̀ mura tan lati yọ́ ninu ìro ẹniti ara rọ̀.
6 Agọ awọn igara ngberú, awọn ti o si nmu Ọlọrun binu wà lailewu, awọn ẹniti o si gbá oriṣa mu li ọwọ wọn.
7 Ṣugbọn nisisiyi, bi awọn ẹranko lere, nwọn o kọ́ ọ li ẹkọ́, ati ẹiyẹ oju ọrun, nwọn o si sọ fun ọ.
8 Tabi, ba ilẹ aiye sọ̀rọ, yio si kọ́ ọ, awọn ẹja inu okun yio si sọ fun ọ.
9 Tani kò mọ̀ ninu gbogbo wọnyi pe, ọwọ Oluwa li o ṣe nkan yi?
10 Lọwọ ẹniti ẹmi ohun alãye gbogbo gbé wà, ati ẹmi gbogbo araiye.
11 Eti ki idán ọ̀rọ wò bi? tabi adùn ẹnu ki isi tọ onjẹ rẹ̀ wò?
12 Awọn arugbo li ọgbọ́n wà fun, ati ninu gigùn ọjọ li oye.
13 Pẹlu rẹ̀ (Ọlọrun) li ọgbọ́n ati agbarà, on ni ìmọ ati oye,
14 Kiyesi i, o biwó, a kò si le igbe ró mọ́, o se enia mọ́, kò si sí iṣisilẹ̀ kan.
15 Kiyesi i, o da awọn omi duro, nwọn si gbẹ, o si rán wọn jade, nwọn si ṣẹ bo ilẹ aiye yipo.
16 Pẹlu rẹ̀ li agbara ati ọgbọ́n, ẹniti nṣìna ati ẹniti imu ni ṣìna tirẹ̀ ni nwọn iṣe.
17 O mu awọn igbimọ̀ lọ nihoho, a si sọ awọn onidajọ di wère.
18 O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja.
19 O mu awọn alufa lọ nihoho, o si tẹ ori awọn alagbara bá.
20 O mu ọ̀rọ-ẹnu ẹni-igbẹkẹle kuro, o si ra awọn àgbàgbà ni iye.
21 O bù ẹ̀gan lu awọn ọmọ-alade, o si tú àmure awọn alagbara.
22 O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀.
23 On a mu orilẹ-ède bi si i, a si run wọn, on a sọ orilẹ-ède di nla, a si tun ṣẹ́ wọn kù.
24 On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si.
25 Nwọn a ma fi ọwọ ta ilẹ ninu òkunkun laisi imọlẹ, on a si ma mu wọn tàse irin bi ọmuti.