1 PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe,
2 A! ibaṣepe emi wà bi igba oṣu ti o kọja, bi ọjọ ti Ọlọrun pa mi mọ́!
3 Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja.
4 Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi.
5 Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka.
6 Nigbati emi nfi ori-amọ wẹ̀ iṣisẹ mi, ati ti apata ntú iṣàn ororo jade fun mi wá.
7 Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro.
8 Nigbana ni awọn ọdọmọkunrin ri mi, nwọn si sapamọ́, awọn àgba dide duro.
9 Awọn ọmọ-alade dakẹ ọ̀rọ sisọ, nwọn a si fi ọwọ wọn le ẹnu.
10 Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn.
11 Nitoripe eti gbọ́ ti emi, a si sure fun mi, oju si ri mi, on a jẹri mi.
12 Nitoriti mo gba talaka ti nsọkun, ati alainibaba, ati alaini oluranlọwọ.
13 Isure ẹniti o fẹrẹ iṣegbe wa si ori mi, emi si mu aiya opo kọrin fun ayọ̀.
14 Emi si mu ododo wọ̀, o si bò mi lara; idajọ mi dabi aṣọ igunwa ati ade ọba.
15 Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún.
16 Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri.
17 Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀.
18 Nigbana ni mo wipe, emi o kú ninu itẹ mi, emi o si mu ọjọ mi pọ̀ si i bi iyanrin. (bi ọjọ ti ẹiyẹ Feniksi.)
19 Gbongbo mi ta lọ si ibi omi, ìri si sẹ̀ si ara ẹká mi titi li oru.
20 Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi.
21 Emi li enia ndẹti silẹ si, nwọn a si duro, nwọn a si dakẹ ninu ìgbimọ mi.
22 Lẹhin ọ̀rọ mi nwọn kò si tun sọ mọ́, ọ̀rọ mi bọ́ si wọn li eti.
23 Nwọn a si duro dè mi bi ẹnipe fun ojo; nwọn si yanu wọn gboro bi ẹnipe fun ojo àrọ-kuro.
24 Emi si rẹrin si wọn nigbati nwọn kò ba gba a gbọ́; imọlẹ oju mi ni nwọn kò le imu rẹ̀wẹsi.
25 Mo la ọ̀na silẹ fun wọn, mo si joko bi Olu, mo si joko bi ọba ninu ogun, bi ẹniti ntù aṣọ̀fọ̀ ninu.