Job 7 YCE

1 NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe?

2 Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀.

3 Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi.

4 Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ.

5 Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni.

6 Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti.

7 A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ.

8 Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́!

9 Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ.

10 Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ.

11 Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi.

12 Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi?

13 Nigbati mo wipe, ibusùn mi yio tù mi lara, itẹ mi yio gbé ẹrù irahùn mi pẹlu.

14 Nigbana ni iwọ fi alá da mi niji, iwọ si fi iran oru dẹrubà mi.

15 Bẹ̃li ọkàn mi yan isà okú jù aye, ikú jù egungun mi lọ.

16 O su mi, emi kò le wà titi: jọwọ mi jẹ, nitoripe asan li ọjọ mi.

17 Kili enia ti iwọ o ma kokìki rẹ̀? ati ti iwọ iba fi gbe ọkàn rẹ le e?

18 Ati ti iwọ o fi ma wa ibẹ̀ ẹ wò li orowurọ̀, ti iwọ o si ma dán a wò nigbakũgba!

19 Yio ti pẹ́ to ki iwọ ki o to fi mi silẹ̀ lọ, ti iwọ o fi jọ mi jẹ titi emi o fi le dá itọ mi mì.

20 Emi ti ṣẹ̀, kili emi o ṣe si ọ, iwọ Olùtọju enia? ẽṣe ti iwọ fi fi mi ṣe àmi itasi niwaju rẹ, bẹ̃li emi si di ẹrù-wuwo si ara rẹ?

21 Ẽṣe ti iwọ kò si dari irekọja mi jì, ki iwọ ki o si mu aiṣedede mi kuro? njẹ nisisiyi li emi iba sùn ninu erupẹ, iwọ iba si wá mi kiri li owurọ̀, emi ki ba ti si.