1 NIGBANA ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe,
2 Tani eyi ti nfi ọ̀rọ aini igbiro ṣú ìmọ li òkunkun.
3 Di ẹgbẹ ara rẹ li amure bi ọkunrin nisisiyi, nitoripe emi o bère lọwọ rẹ ki o si da mi lohùn.
4 Nibo ni iwọ wà nigbati mo fi ipilẹ aiye sọlẹ? wi bi iwọ ba moye!
5 Tali o fi ìwọn rẹ̀ lelẹ, bi iwọ ba mọ̀, tabi tani o ta okun wiwọn sori rẹ̀.
6 Lori ibo ni a gbe kan ipilẹ rẹ̀ mọ́, tabi tali o fi okuta igun rẹ̀ le ilẹ?
7 Nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ̀?
8 Tabi tali o fi ilẹkun sé omi okun mọ́, nigbati o ya jade bi ẹnipe o ti inu tu jade wá?
9 Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀?
10 Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun.
11 Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.
12 Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀?
13 Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀.
14 Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa.
15 A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́.
16 Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla?
17 A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú?
18 Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀?
19 Ọ̀na wo ni imọlẹ igbé, bi o ṣe ti òkunkun, nibo ni ipò rẹ̀?
20 Ti iwọ o fi mu u lọ si ibi àla rẹ̀, ti iwọ o si le imọ̀ ipa-ọ̀na lọ sinu ile rẹ̀?
21 Iwọ mọ̀ eyi, nitoriti ni igbana ni a bi ọ? ati iye ọjọ rẹ si pọ!
22 Iwọ ha wọ inu iṣura ojò-dídì lọ ri bí, iwọ si ri ile iṣura yinyin ri?
23 Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà.
24 Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye?
25 Tali o la ipado fun ẹkún iṣan omi, ati ọ̀na fun manamana ãrá?
26 Lati mu u rọ̀jo sori aiye, nibiti enia kò si, ni aginju nibiti enia kò si.
27 Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade?
28 Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri?
29 Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i?
30 Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀.
31 Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu?
32 Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?
33 Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?
34 Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?
35 Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!
36 Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya?
37 Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade.
38 Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀?
39 Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun?
40 Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ.
41 Tani npese ohun jijẹ fun ìwo? nigbati awọn ọmọ rẹ̀ nkepe Ọlọrun, nwọn a ma fò kiri nitori aili ohun jijẹ.