Job 19 YCE

1 NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe,

2 Yio ti pẹ to ti ẹnyin o fi ma bà mi ninu jẹ, ti ẹnyin o fi ma fi ọ̀rọ kun mi ni ìjanja?

3 Igba mẹwa li ẹnyin ti ngàn mi, oju kò tì nyin ti ẹ fi jẹ mi niya.

4 Ki a fi sí bẹ̃ pe, mo ṣìna nitõtọ, ìṣina mi wà lara emi tikarami.

5 Bi o tilẹ ṣepe ẹnyin o ṣogo si mi lori nitõtọ, ti ẹ o si ma fi ẹ̀gan mi gun mi loju.

6 Ki ẹ mọ̀ nisisiyi pe: Ọlọrun li o bì mi ṣubu, o si nà àwọn rẹ̀ yi mi ka.

7 Kiyesi i, emi nkigbe pe, Ọwọ́ alagbara! ṣugbọn a kò gbọ́ ti emi; mo kigbe soke, bẹ̃ni kò si idajọ.

8 O sọ̀gba di ọ̀na mi ti emi kò le kọja, o si mu òkunkun ṣú si ipa ọ̀na mi:

9 O ti bọ́ ogo mi, o si ṣi ade kuro li ori mi.

10 O ti bà mi jẹ ni iha gbogbo, ẹmi si pin; ireti mi li a o si fatu bi igi:

11 O si tinabọ ibinu rẹ̀ si mi, o si kà mi si bi ọkan ninu awọn ọta rẹ̀.

12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ si dàpọ si mi, nwọn si tẹgun si mi, nwọn si dó yi agọ mi ka.

13 O mu awọn arakunrin mi jina si mi rére, ati awọn ojulumọ mi di ajeji si mi nitõtọ.

14 Awọn ajọbi mi fà sẹhin, awọn afaramọ́ ọrẹ mi si di onigbagbe mi.

15 Awọn ara inu ile mi ati awọn ọmọbinrin iranṣẹ mi kà mi si ajeji, emi jasi ajeji enia li oju wọn.

16 Mo pè iranṣẹ mi, on kò si da mi lohùn, mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ.

17 Ẹmi mi sú aya mi, ati õrùn mi sú awọn ọmọ inu iya mi.

18 Ani awọn ọmọde fi mi ṣẹsin: mo dide, nwọn si sọ̀rọ ẹ̀gan si mi.

19 Gbogbo awọn ọrẹ idimọpọ mi korira mi, awọn olufẹ mi si kẹ̀hinda mi.

20 Egungun mi lẹ mọ́ awọ ara mi ati mọ́ ẹran ara mi, mo si bọ́ pẹlu awọ ehin mi.

21 Ẹ ṣãnu fun mi, ẹ ṣãnu fun mi, ẹnyin ọrẹ mi, nitori ọwọ Ọlọrun ti bà mi.

22 Nitori kili ẹnyin ṣe lepa mi bi Ọlọrun, ti ẹran ara mi kò tẹ́ nyin lọrùn!

23 A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe!

24 Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai.

25 Ati emi, emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ li ãyè, ati pe on bi Ẹni-ikẹhin ni yio dide soke lori erupẹ ilẹ.

26 Ati lẹhin igba awọ ara mi, ti a ti ke e kuro bi iru eyi, ati laili ẹran ara mi li emi o ri Ọlọrun,

27 Ẹniti emi o ri fun ara mi, ti oju mi o si wò, kì si iṣe ti ẹlomiran; ọkàn mi si dáku ni inu mi.

28 Bi ẹnyin ba wipe, Awa o ti lepa rẹ̀ to! ati pe, gbongbo ọ̀rọ na li a sa ri li ọwọ mi,

29 Ki ẹnyin ki o bẹ̀ru idà; nitoripe ibinu ni imu ijiya idà wá: ki ẹnyin ki o lè imọ̀ pe idajọ kan mbẹ.