Job 27 YCE

1 PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe,

2 Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ.

3 Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi.

4 Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan.

5 Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi.

6 Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi.

7 Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo.

8 Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade.

9 Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i?

10 On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?

11 Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ.

12 Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃?

13 Eyi ni ipín enia buburu lọdọ Ọlọrun, ati ogún awọn aninilara, ti nwọn o gbà lọwọ Olodumare.

14 Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ.

15 Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún.

16 Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀.

17 Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na.

18 On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa.

19 Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si.

20 Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru.

21 Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀.

22 Nitoripe Olodumare yio kọlù u, kì o sì dasi; on iba yọ̀ lati sá kuro li ọwọ rẹ̀.

23 Awọn enia yio si ṣapẹ si i lori, nwọn o si ṣe ṣiọ si i kuro ni ipò rẹ̀.