Job 31 YCE

1 EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia?

2 Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá?

3 Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ?

4 On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi?

5 Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan.

6 Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi.

7 Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ.

8 Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu.

9 Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ ibadeni li ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi,

10 Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀.

11 Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ.

12 Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu.

13 Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà;

14 Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá?

15 Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu?

16 Bi mo ba fà ọwọ sẹhin fun ifẹ-inu talaka, tabi bi mo ba si mu oju opó mofo;

17 Tabi ti mo ba nikan bu òkele mi jẹ, ti alainibaba kò jẹ ninu rẹ̀;

18 Nitoripe lati igba ewe mi wá li a ti tọ́ ọ dàgba pẹlu mi bi ẹnipe baba, emi si nṣe itọju rẹ̀ (opó) lati inu iya mi wá.

19 Bi emi ba ri olupọnju laini aṣọ, tabi talaka kan laini ibora;

20 Bi ẹgbẹ rẹ̀ kò ba sure fun mi, tabi bi ara rẹ̀ kò si gbona nipasẹ irun agutan mi.

21 Bi mo ba si gbe ọwọ mi soke si alainibaba, nitoripe mo ri iranlọwọ mi li ẹnu-bode,

22 Njẹ ki apá mi ki o wọ́n kuro li ọkọ́ ejika rẹ̀, ki apá mi ki o si ṣẹ́ lati egungun rẹ̀ wá.

23 Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro.

24 Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi;

25 Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ;

26 Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ,

27 Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi:

28 Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke.

29 Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a.

30 Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀.

31 Bi awọn enia inu agọ mi kò ba le wipe, Tali o le ri ẹniti agbo-ẹran rẹ̀ kò tẹlọrùn?

32 Alejo kò wọ̀ ni igboro ri, emi ṣi ilẹkun mi silẹ fun èro.

33 Bi mo ba bò irekọja mi mọlẹ bi Adamu, ni pipa ẹbi mi mọ́ li aiya mi:

34 Ọ̀pọlọpọ enia ni mo ha bẹ̀ru bi, tabi ẹ̀gan awọn idile ni mba mi li ẹ̀ru? ti mo fi pa ẹnu mọ́, ti emi kò si fi jade sode?

35 Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ!

36 Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi.

37 Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀.

38 Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun,

39 Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ,

40 Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.)