1 O si tun di ijọ kan nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wá ipé niwaju Oluwa, Satani si wá pẹlu wọn, lati pé niwaju Oluwa.
2 Oluwa si bi Satani pe, nibo ni iwọ ti wá? Satani si dá Oluwa lohùn pe, lati ilọ siwá sẹhin lori ilẹ aiye ati ni irinkerindo ninu rẹ̀.
3 Oluwa si wi fun Satani pe, iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ li aiye, ọkunrin ti iṣe olõtọ ti o si duro ṣinṣin, ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ti o si korira ìwa buburu, bẹ̃li o si di ìwa otitọ rẹ̀ mu ṣinṣin, bi iwọ tilẹ ti dẹ mi si i lati run u lainidi.
4 Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀.
5 Ṣugbọn nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ egungun rẹ̀ ati ara rẹ̀, bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.
6 Oluwa si wi fun Satani pe, Wõ, o mbẹ ni ikawọ rẹ, ṣugbọn dá ẹmi rẹ̀ si.
7 Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀.
8 O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru.
9 Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú.
10 Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.
11 Nigbati awọn ọrẹ Jobu mẹta gburo gbogbo ibi ti o ba a, nwọn wá, olukuluku lati ibujoko rẹ̀ wá; Elifasi, ara Tema, a si Bildadi, ara Ṣua, ati Sofari, ara Naama: nitoripe nwọn ti dajọ ipade pọ̀ lati ba a ṣọ̀fọ on ati ṣipẹ fun u.
12 Nigbati nwọn si gboju wọn wò li òkere rére, ti nwọn kò si mọ̀ ọ, nwọn gbe ohùn wọn soke, nwọn sọkun: olukuluku si fa aṣọ igunwa rẹ̀ ya, nwọn si kù erupẹ si oju ọrun si ara wọn lori.
13 Bẹ̃ni nwọn joko tì i ni ilẹyilẹ ni ijọ meje ti ọ̀san ti oru, ẹnikẹni kò si ba a dá ọ̀rọ kan sọ nitoriti nwọn ri pe, ibinujẹ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.