Job 34 YCE

1 PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe,

2 Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye.

3 Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò.

4 Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa.

5 Nitoripe Jobu wipe, Olododo li emi; Ọlọrun si ti gbà idajọ mi lọ.

6 Emi ha lè ipurọ si itọsí mi bi, ọfa mi kò ni awọtan, laiṣẹ ni.

7 Ọkunrin wo li o dabi Jobu, ti nmu ẹ̀gan bi ẹni mu omi.

8 Ti mba awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ kẹgbẹ, ti o si mba awọn enia buburu rin.

9 Nitori o sa ti wipe, Ère kan kò si fun enia, ti yio fi ma ṣe inu didun si Ọlọrun,

10 Njẹ nitorina, ẹ fetisilẹ si mi, ẹnyin enia amoye: odõdi fun Ọlọrun ti iba fi huwa buburu, ati fun Olodumare, ti yio fi ṣe aiṣedede!

11 Nitoripe ẹsan iṣẹ enia ni yio san fun u, yio si mu olukuluku ki o ri gẹgẹ bi ipa-ọ̀na rẹ̀.

12 Nitõtọ Ọlọrun kì yio hùwakiwa, bẹ̃ni Olodumare kì yio yi idajọ po.

13 Tani o fi itọju aiye lé e lọwọ, tabi tali o to gbogbo aiye lẹsẹlẹsẹ?

14 Bi o ba gbe aiya rẹ̀ le kiki ara rẹ̀, ti o si gba ọkàn rẹ̀ ati ẹmi rẹ̀ sọdọ ara rẹ̀,

15 Gbogbo enia ni yio parun pọ̀, enia a si tun pada di erupẹ.

16 Njẹ nisisiyi, bi iwọ ba ni oye, gbọ́ eyi, fetisi ohùn ẹnu mi.

17 Ẹniti o korira otitọ le iṣe olori bi? iwọ o ha si da olõtọ-ntọ̀ lẹbi?

18 O ha tọ́ lati wi fun ọba pe, Enia buburu ni iwọ, tabi fun awọn ọmọ-alade pe, Alaimọ-lọrun li ẹnyin?

19 Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe.

20 Ni iṣẹju kan ni nwọn o kú, awọn enia a si di yiyọ lẹnu larin ọganjọ, nwọn a si kọja lọ; a si mu awọn alagbara kuro laifi ọwọ́ ṣe.

21 Nitoripe oju rẹ̀ mbẹ ni ipa-ọ̀na enia, on si ri irin rẹ̀ gbogbo.

22 Kò si òkunkun, tabi ojiji ikú, nibiti awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio gbe sapamọ si.

23 Nitoripe on kò pẹ ati kiyesi ẹnikan, ki on ki o si mu u lọ sinu idajọ niwaju Ọlọrun.

24 On o fọ awọn alagbara tútu laini-iwadi, a si fi ẹlomiran dipo wọn,

25 Nitoripe o mọ̀ iṣẹ wọn, o si yi wọn po di oru, bẹ̃ni nwọn di itẹrẹ́ pọ̀.

26 O kọlu wọn bi enia buburu, nibiti awọn ẹlomiran ri i.

27 Nitorina ni nwọn pada kẹhinda si i, nwọn kò si ti fiyesi ipa-ọ̀na rẹ̀ gbogbo.

28 Ki nwọn ki o si mu igbe ẹkún awọn talaka lọ de ọdọ rẹ̀, on si gbọ́ igbe ẹkún olupọnju.

29 Nigbati o ba fun ni ni irọra, tani yio da a lẹbi, nigbati o ba pa oju rẹ̀ mọ, tani yio le iri i? bẹ̃ni o ṣe e si orilẹ-ède tabi si enia kanṣoṣo.

30 Ki agabagebe ki o má ba jọba, ki nwọn ki o má di idẹwo fun enia.

31 Nitoripe ẹnikan ha le wi fun Ọlọrun pe, emi jiya laiṣẹ̀?

32 Eyi ti emi kò ri, iwọ fi kọ́ mi, bi mo ba si dẹṣẹ, emi kì yio ṣe bẹ̃ mọ́.

33 Iṣe bi ti inu rẹ pe, on o san ẹ̀san pada? njẹ on yio san a pada, iwọ iba kọ̀ ọ tabi iwọ iba fẹ ẹ, kì iṣe emi, pẹlupẹlu kili iwọ mọ̀, sọ ọ!

34 Awọn enia amoye yio wi fun mi, ati pẹlupẹlu ẹnikẹni ti nṣe ọlọgbọ́n, ti o si gbọ́ mi.

35 Jobu ti fi aimọ̀ sọ̀rọ, ọ̀rọ rẹ̀ si ṣe alaigbọ́n.

36 Ifẹ mi ni ki a dán Jobu wò de opin, nitori idahùn rẹ̀ nipa ọ̀na enia buburu;

37 Nitoripe o fi iṣọtẹ kún ẹ̀ṣẹ rẹ̀, o papẹ́ li awujọ wa, o si sọ ọ̀rọ pupọ si Ọlọrun.