Job 3 YCE

Jobu Ráhùn sí Ọlọrun

1 LẸHIN eyi ni Jobu yanu o si fi ọjọ ibi rẹ̀ ré.

2 Jobu sọ, o si wipe,

3 Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan.

4 Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i.

5 Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya.

6 Ki òkunkun ki o ṣúbo oru na biribiri, ki o má ṣe yọ̀ pẹlu ọjọ ọdun na: ki a má ṣe kà a mọ iye ọjọ oṣù.

7 Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ.

8 Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke.

9 Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́.

10 Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi.

11 Ẽṣe ti emi kò fi kú lati inu wá, tabi ti emi kò fi pin ẹmi nigbati mo ti inu jade wá?

12 Ẽṣe ti ẽkun wá pade mi, tabi ọmu ti emi o mu?

13 Njẹ! nisisiyi, emi iba ti dubulẹ̀ jẹ, emi a si dakẹ, emi iba ti sùn: njẹ emi iba ti simi!

14 Pẹlu awọn ọba ati igbimọ aiye, ti o mọle takete fun ara wọn.

15 Tabi pẹlu awọn ọmọ-alade ti o ni wura, ti nwọn si fi fadakà kún inu ile wọn.

16 Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ.

17 Nibẹ ni ẹni-buburu ṣiwọ iyọnilẹnu, nibẹ ẹni-ãrẹ̀ wà ninu isimi.

18 Nibẹ ni awọn ìgbekun simi pọ̀, nwọn kò si gbohùn amunisìn mọ́.

19 Ati ewe ati àgba wà nibẹ, ẹru si di omnira kuro lọwọ olowo rẹ̀.

20 Nitori kili a ṣe fi imọlẹ fun otoṣi, ati ìye fun ọlọkàn kikoro.

21 Ti nwọn duro de ikú, ṣugbọn on kò wá, ti nwọn wàlẹ wá a jù fun iṣura ti a bò mọlẹ pamọ.

22 Ẹniti o yọ̀ gidigidi, ti inu wọn si dùn nigbati nwọn ba le wá isa-okú ri.

23 Kili a fi imọlẹ fun ẹniti ọ̀na rẹ̀ lumọ si, ti Ọlọrun si sọgba di mọ ká?

24 Nitoripe imi-ẹ̀dun mi ṣaju ki nto jẹun, ikerora mi si tú jade bi omi.

25 Nitoripe ohún na ti mo bẹ̀ru gidigidi li o de ba mi yi, ẹ̀ru ohun ti mo bà li o si de si mi yi.

26 Emi kò wà lailewu rí, bẹ̃li emi kò ni isimi, bẹ̃li emi kò ni ìfaiyabalẹ, asiwá-asibọ̀ iyọnu de.