Job 4 YCE

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni

1 NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,

2 Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ?

3 Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le.

4 Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera.

5 Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀.

6 Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ?

7 Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri?

8 Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na.

9 Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun.

10 Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka.

11 Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.

12 Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀.

13 Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia.

14 Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé.

15 Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan.

16 On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe:

17 Ẹni kikú le jẹ olododo niwaju Ọlọrun, enia ha le mọ́ ju Ẹlẹda rẹ̀ bi?

18 Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ.

19 Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro.

20 A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si.

21 A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.