7 Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? iwọ le ri idi Olodumare de pipé rẹ̀?
8 O dabi giga ọrun, kini iwọ le iṣe? o jinlẹ jù ipo-okú lọ, kini iwọ le imọ̀?
9 Ìwọn rẹ̀ gùn jù aiye lọ, o si ni ìbu jù okun lọ.
10 Bi on ba rekọja, ti o si sénà, tabi ti o si ṣe ikojọpọ, njẹ tani yio da a pada kuro?
11 On sa mọ̀ enia asan, o ri ìwa-buburu pẹlu, on kò si ni ṣe lãlã lati ṣà a rò.
12 Enia lasan a sa ma fẹ iṣe ọlọgbọ́n, bi a tilẹ ti bi enia bi ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
13 Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀.