14 Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de.
15 Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ.
16 Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi.
17 A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀.
18 Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀.
19 Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo.
20 Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro.