9 Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko.
10 Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da?
11 Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ.
12 Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn.
13 A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi.
14 Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de.
15 Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ.