11 Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ.
12 Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀.
13 Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ.
14 Ibajẹ lori ibajẹ li o fi ba mi jẹ; o sure kọlù mi bi òmirán.
15 Mo rán aṣọ-apo bò ara mi, mo si rẹ̀ iwo mi silẹ ninu erupẹ.
16 Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi.
17 Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu.