3 Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn.
4 Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin.
5 Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin.
6 Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de?
7 Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete.
8 Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju.
9 Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi.