1 EMI mi bajẹ, ọjọ mi parun, isa-okú duro dè mi.
2 Nitõtọ! awọn ẹlẹya wà lọdọ mi, oju mi si tẹmọ́ imunibinu wọn.
3 Njẹ nisisiyi, fi lelẹ! yàn onigbọwọ fun mi lọdọ rẹ; tani oluwa rẹ̀ ti yio ba mi so ọwọ pọ̀?
4 Nitoripe iwọ ti sé wọn laiya kuro ninu oye, nitorina iwọ kì yio gbé wọn leke.