6 O si sọ mi di ẹni-owe fun awọn enia, niwaju wọn ni mo dabi ẹni itutọ́ si li oju.
7 Oju mi ṣú baibai pẹlu nitori ibinujẹ, gbogbo ẹ̀ya ara mi si dabi ojiji.
8 Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe.
9 Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju.
10 Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin.
11 Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi.
12 A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de.