8 Awọn olododo yio yanu si eyi, ẹni alaiṣẹ̀ si binu si awọn àgabagebe.
9 Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju.
10 Ṣugbọn bi o ṣe ti gbogbo nyin, ẹ yipada, ki ẹ si tun bọ̀ nisisiyi, emi kò le ri ọlọgbón kan ninu nyin.
11 Ọjọ ti emi ti kọja, iro mi ti fà já, ani iro inu mi.
12 A sọ oru di ọ̀san; nwọn ni, imọlẹ sunmọ ibiti òkunkun de.
13 Bi mo tilẹ ni ireti, ipo-okú ni ile mi, mo ti tẹ bùsun mi sinu òkunkun.
14 Emi ti wi fun idibajẹ pe, Iwọ ni baba mi, ati fun kòkoro pe, Iwọ ni iya mi ati arabinrin mi.