15 Yio si ma joko ninu agọ rẹ̀ eyi ti kì iṣe tirẹ̀, imi-õrùn li a ọ fún kakiri si ara ile rẹ̀.
16 Gbongbo rẹ̀ yio gbẹ nisalẹ, a o si ke ẹ̀ka rẹ̀ kuro loke.
17 Iranti rẹ̀ yio parun kuro li aiye, kì yio si orukọ rẹ̀ ni igboro ilu.
18 A o si le e lati inu imọlẹ sinu òkunkun, a o si le e kuro li aiye.
19 Kì yio ni ọmọ bibikunrin tabi ajọbi-kunrin ninu awọn enia rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹnikan ti o kù ninu agbo ile rẹ̀.
20 Ẹnu yio ya awọn iran ti ìwọ-õrùn si igba ọjọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ru iwariri ti ba awọn iran ti ila-õrùn.
21 Nitõtọ iru-bẹ̃ ni ibujoko awọn enia buburu, eyi si ni ipo ẹni ti kò mọ̀ Ọlọrun.