6 Imọlẹ yio ṣokunkun ninu agọ rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o si pa pẹlu rẹ̀.
7 Irin ẹsẹ agbara rẹ̀ yio di fifọn, ìmọ on tikararẹ ni yio bi i ṣubu.
8 Nipa ẹsẹ on tikararẹ̀ o ti bọ́ sinu àwọn, o si rìn lori okùn didẹ.
9 Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀.
10 A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na.
11 Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀.
12 Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀.