9 Okùn ẹgẹ́ ni yio mu u ni gigĩsẹ, awọn igara yio si ṣẹgun rẹ̀.
10 A dẹkùn silẹ fun u lori ilẹ, a si wà ọ̀fin fun u loju ọ̀na.
11 Ẹ̀ru nla yio bà a ni iha gbogbo, yio si le e de ẹsẹ rẹ̀.
12 Ailera rẹ̀ yio di pipa fun ebi, iparun yio dide duro si i ni iha rẹ̀.
13 Yio jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀, akọbi ikú ni yio jẹ agbara rẹ̀ run.
14 Eyi ti o ti gbẹkẹle ni a o fàtu kuro ninu agọ rẹ̀, yio si tọ̀ ọba ẹ̀ru nla nì lọ.
15 Yio si ma joko ninu agọ rẹ̀ eyi ti kì iṣe tirẹ̀, imi-õrùn li a ọ fún kakiri si ara ile rẹ̀.