4 Satani si dá Oluwa lohùn wipe, awọ fun awọ; ani ohun gbogbo ti enia ni, on ni yio fi rà ẹmi rẹ̀.
5 Ṣugbọn nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ egungun rẹ̀ ati ara rẹ̀, bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.
6 Oluwa si wi fun Satani pe, Wõ, o mbẹ ni ikawọ rẹ, ṣugbọn dá ẹmi rẹ̀ si.
7 Bẹ̃ni Satani jade lọ kuro niwaju Oluwa, o si sọ Jobu li õwo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ de atari rẹ̀.
8 O si mu apadì o fi nhá ara rẹ̀, o si joko ninu ẽru.
9 Nigbana ni aya rẹ̀ wi fun u pe, iwọ di ìwa otitọ rẹ mu sibẹ! bu Ọlọrun, ki o si kú.
10 Ṣugbọn on da a lohùn pe, iwọ sọ̀rọ bi ọkan ninu awọn obinrin alaimoye ti isọ̀rọ; kinla! awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má si gba ibi! Ninu gbogbo eyi Jobu kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.