16 O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a.
17 Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́.
18 Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀.
19 Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́.
20 Nitori on kò mọ̀ iwa-pẹlẹ ninu ara rẹ̀, ki yio si gbà ninu eyiti ọkàn rẹ̀ fẹ silẹ.
21 Ohun kan kò kù fun jijẹ rẹ̀, nitorina ọrọ̀ rẹ̀ kì yio duro pẹ́.
22 Ninu titó ìkún rẹ̀ yio wà ninu ihale, ọwọ gbogbo awọn oniyọnu ni yio dide si i lori.