3 Mo ti gbọ́ ẹsan ẹ̀gan mi, ẹmi oye mi si da mi lohùn.
4 Iwọ kò mọ̀ eyi ri ni igba atijọ, lati igba ti a sọ enia lọjọ̀ silẹ aiye?
5 Pe, orin ayọ̀ enia buburu igba kukuru ni, ati pe, ni iṣẹju kan li ayọ̀ àgabagebe.
6 Bi ọlanla rẹ̀ tilẹ goke de ọrun, ti ori rẹ̀ si kan awọsanma.
7 Ṣugbọn yio ṣegbe lailai bi igbẹ́ ara rẹ̀; awọn ti o ti ri i rí, yio wipe, On ha dà?
8 Yio fò lọ bi alá, a kì yio si ri i, ani a o lé e lọ bi iran oru.
9 Oju ti o ti ri i rí pẹlu, kì yio si ri i mọ́, bẹ̃ni ibujoko rẹ̀ kì yio si ri i mọ́.