22 Ẹnikẹni le ikọ́ Ọlọrun ni ìmọ? on ni sa nṣe idajọ ẹni ibi giga.
23 Ẹnikan a kú ninu pipé agbara rẹ̀, ti o wà ninu irọra ati idakẹ patapata.
24 Ọpọ́n rẹ̀ kún fun omi-ọmú, egungun rẹ̀ si tutu fun ọra.
25 Ẹlomiran a si kú ninu kikoro ọkàn rẹ̀, ti kò si fi inu didun jẹun.
26 Nwọn o dubulẹ bakanna ninu erupẹ, kòkoro yio si ṣùbo wọn.
27 Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi.
28 Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà?