4 Bi o ṣe ti emi ni, aroye mi iṣe si enia bi, tabi ẽtiṣe ti ọkàn mi kì yio fi ṣe aibalẹ?
5 Ẹ wò mi fin, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki ẹ si fi ọwọ le ẹnu nyin.
6 Ani nigbati mo ranti, ẹ̀ru bà mi, iwarìri si mu mi lara.
7 Nitori kini enia buburu fi wà li ãyè, ti nwọn gbọ́, ani ti nwọn di alagbara ni ipa!
8 Iru-ọmọ wọn fi idi kalẹ li oju wọn pẹlu wọn, ati ọmọ-ọmọ wọn li oju wọn.
9 Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn.
10 Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu;