14 Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun.
15 Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn.
16 Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn.
17 Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn.
18 Sibẹ o fi ohun rere kún ile wọn! ṣugbọn ìmọ enia-buburu jìna si mi!
19 Awọn olododo ri i, nwọn si yọ̀, awọn alailẹ̀ṣẹ si fi wọn rẹrin ẹlẹya pe:
20 Lotitọ awọn ọta wa ni a ke kuro, iná yio si jó iyokù wọn run.