4 Yio ha ba ọ wi bi nitori ìbẹru Ọlọrun rẹ, yio ha ba ọ lọ sinu idajọ bi?
5 Iwa-buburu rẹ kò ha tobi, ati ẹ̀ṣẹ rẹ lainiye?
6 Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn.
7 Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa.
8 Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀.
9 Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́.
10 Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu.