6 Nitõtọ iwọ gbà ohun ẹri li ọwọ arakunrin rẹ lainidi, iwọ si tú onihoho li aṣọ wọn.
7 Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa.
8 Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀.
9 Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́.
10 Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu.
11 Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ?
12 Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó!