2 Bawo ni iwọ nṣe iranlọwọ ẹniti kò ni ipá, bawo ni iwọ nṣe gbà apa ẹniti kò li agbara?
3 Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri?
4 Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?
5 Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6 Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.
7 On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.
8 O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.