4 Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?
5 Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6 Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.
7 On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.
8 O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.
9 O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori.
10 O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.