1 PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe,
2 A! ibaṣepe emi wà bi igba oṣu ti o kọja, bi ọjọ ti Ọlọrun pa mi mọ́!
3 Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja.
4 Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi.
5 Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka.
6 Nigbati emi nfi ori-amọ wẹ̀ iṣisẹ mi, ati ti apata ntú iṣàn ororo jade fun mi wá.
7 Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro.