11 O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo.
12 Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ!
13 Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀?
14 Nitoripe Ọlọrun sọ̀rọ lẹkan, ani lẹkeji ṣugbọn enia kò roye rẹ̀.
15 Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun.
16 Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn.
17 Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia.