28 O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ!
29 Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta,
30 Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i.
31 Jobu! kiyesi i gidigidi, ki o si fetisilẹ si mi; pa ẹnu rẹ mọ́, emi o si ma sọ!
32 Bi iwọ ba si ni ohun iwi, da mi lohùn, mã sọ, nitoripe emi nfẹ da ọ lare.
33 Bi bẹ̃ kọ̀, gbọ temi, pa ẹnu rẹ mọ́; emi o si kọ́ ọ li ọgbọ́n.