7 Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara.
8 Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe,
9 Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi.
10 Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀.
11 O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo.
12 Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ!
13 Nitori kini iwọ ṣe mba a jà pe: on kì isọrọ̀kọrọ kan nitori iṣẹ rẹ̀?