3 Nitoriti iwọ wipe, Ère kini yio jasi fun ọ, tabi ère kili emi o fi jẹ jù ère ẹ̀ṣẹ mi lọ?
4 Emi o da ọ lohùn ati awọn ẹgbẹ rẹ pẹlu rẹ.
5 Ṣiju wò ọrun, ki o ri i, ki o si bojuwo awọsanma ti o ga jù ọ lọ.
6 Bi iwọ ba ṣẹ̀ kini iwọ fi ṣe si i? tabi bi irekọja rẹ di pupọ, kini iwọ fi eyini ṣe si i?
7 Bi iwọ ba si ṣe olododo, kini iwọ fi bùn u, tabi kili on ri gbà lati ọwọ rẹ wá?
8 Ìwa buburu rẹ ni fun enia bi iwọ; ododo rẹ si ni fun ọmọ enia.
9 Nipa ọ̀pọlọpọ ininilara nwọn mu ni kigbe, nwọn kigbe nitori apá awọn alagbara.