6 Bi iwọ ba ṣẹ̀ kini iwọ fi ṣe si i? tabi bi irekọja rẹ di pupọ, kini iwọ fi eyini ṣe si i?
7 Bi iwọ ba si ṣe olododo, kini iwọ fi bùn u, tabi kili on ri gbà lati ọwọ rẹ wá?
8 Ìwa buburu rẹ ni fun enia bi iwọ; ododo rẹ si ni fun ọmọ enia.
9 Nipa ọ̀pọlọpọ ininilara nwọn mu ni kigbe, nwọn kigbe nitori apá awọn alagbara.
10 Ṣugbọn kò si ẹniti o wipe, Nibo ni Ọlọrun Ẹlẹda mi wà, ti o fi orin fun mi li oru?
11 Ti on kọ́ wa li ẹkọ́ jù awọn ẹranko aiye lọ, ti o si mu wa gbọ́n jù awọn ẹiyẹ oju ọrun lọ.
12 Nigbana ni nwọn ke, ṣugbọn Ọlọrun kò dahùn nitori igberaga awọn enia buburu.