14 Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la.
15 Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu.
16 Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀.
17 On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin.
19 On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ.
20 Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire.