16 Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀.
17 On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18 Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin.
19 On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ.
20 Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire.
21 O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ.
22 Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri.