12 O yi ìmọ awọn alarekerekè po, bẹ̃li ọwọ wọn kò lè imu idawọle wọn ṣẹ.
13 O mu awọn ọlọgbọ́n ninu arekereke ara wọn, ati ìmọ awọn onroro li o tãri ṣubu li ògedengbè.
14 Nwọn sure wọ inu òkunkun li ọ̀san, nwọn si nfọwọ talẹ̀ li ọ̀sangangan bi ẹnipe li oru.
15 Ṣugbọn o gba talakà là kuro li ọwọ idà, lọwọ ẹnu wọn, ati lọwọ awọn alagbara.
16 Bẹ̃ni abá wà fun talaka, aiṣotitọ si pa ẹnu rẹ̀ mọ.
17 Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare.
18 Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina.