17 Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare.
18 Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina.
19 Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ.
20 Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà.
21 A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé.
22 Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye.
23 Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia.