3 Emi ti ri alaimoye ti o ta gbongbò mulẹ̀, ṣugbọn lojukanna mo fi ibujoko rẹ̀ bú.
4 Awọn ọmọ rẹ̀ kò jina sinu ewu, a si tẹ̀ wọn mọlẹ loju ibode, bẹ̃ni kò si alãbò kan.
5 Ikore oko ẹniti awọn ẹniti ebi npa jẹrun, ti nwọn si wọnú ẹ̀gun lọ ikó, awọn igara si gbe ohùn ini wọn mì.
6 Bi ipọnju kò tilẹ̀ tinu erupẹ jade wá nì, ti iyọnu kò si tinu ilẹ hù jade wá.
7 Ṣugbọn a bi enia sinu wàhala, gẹgẹ bi ìpẹpẹ iná ti ima ta sokè.
8 Sọdọ Ọlọrun li emi lè ma ṣe awári, li ọwọ Ọlọrun li emi lè ma fi ọ̀ran mi le.
9 Ẹniti o ṣe ohun ti o tobi, ti a kò lè iṣe awári, ohun iyanu laini iye.