10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.
12 Òun yóò gbé àṣíá sókè fún àwọn orílẹ̀ èdè,yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì jọ,yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà tí a ti fọ́n káàkiri jọ,láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
13 Owú jíjẹ Éfáímù yóò pòórá,àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó ké kúrò,Éfáímù kò ní jowúu Júdà,tàbí Júdà kó dojú kọ Éfáímù.
14 Wọn yóò dìgbòlu àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́Fílísítíà ni apá ìwọ̀ oòrùn,wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọnènìyàn apá ìlà oòrùn.Wọn yóò gbé ọwọ́ọ wọn lé Édómù àti Móábù,àwọn ará Ámónì yóò sì di ìwẹ̀fàa wọn.
15 Olúwa yóò sọ di gbígbéàyasí òkun Éjíbítì,pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ọ rẹ̀,kọjá lórí odò Éúfírétì.Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méjetó fi jẹ́ pé àwọn ènìyànyóò máa là á kọjá pẹ̀lúu bàtà.
16 Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kùtí ó kù sílẹ̀ ní Ásíríà,gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Ísírẹ́lìnígbà tí wọ́n gòkè láti Éjíbítì wá.