5 Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ ká.
6 Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìúnàti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti béárì yóò máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,kìnnìún yóò sì máa jẹ koríkogẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
8 Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,Ọmọdé yóò ki ọwọ́ọ rẹ̀ bọ ìtẹ́ẹ paramọ́lẹ̀.
9 Wọn kò ní ṣeni lọ́ṣẹ́ tàbí panirunní gbogbo òkè mímọ́ mi,nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwagẹ́gẹ́ bí omi ti í bo òkun.
10 Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jéésè yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àṣíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀ èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.
11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Ásíríà wá, láti ìsàlẹ̀ Éjíbítì àti Òke Éjíbítì, láti Kúṣì, láti Élámù láti Babilóníà, láti Hámátì àti láti àwọn erékùṣù inú òkun.