2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,Èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omiláti inú un kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,Jẹ́ kí ó di mímọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,ohun tí ó ti ṣekí o sì kéde pé a ti gbéorúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mímọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe ṣókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì,nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kanṣoṣoti Ísírẹ́lì láàrin yín.”