8 Nípa ogun-jíjà àti lílé nílùú ni ófi dojú kọ ọ́pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà oorùn fẹ́
9 Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wàfún ẹ̀ṣẹ̀ Jákọ́bù,èyí ni yóò sì jẹ́ èṣo kíkún tiìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ:Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹdàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,kì yóò sí ọ̀pá Áṣérà tàbí pẹpẹ tùràrítí yóò wà ní ìdúró.
10 Ìlú olódi náà ti dahoro,ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀tìgẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀;níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹkoníbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
11 Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ gbẹ, a kán wọn dànùàwọn obìnrin wá wọ́n, sì fi wọ́n dánánítorí àwọn ènìyàn tí òye kò yéni wọ́n jẹ́;Nítorí náà ni Ẹlẹ́dàá wọn kò ṣe yọ́nú sí wọn.Ẹlẹ́dàá wọn kò sì síjú àánú wò wọ́n.
12 Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó ooré láti ìṣàn omi Éúfírétì wá títí dé Wádì ti Éjíbítì, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Ísírẹ́lì, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
13 Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Ásíríà àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Éjíbítì yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.