9 Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sódómù;wọn ò fi pamọ́!Ègbé ni fún wọn!Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
10 Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èṣo iṣẹ́ ẹ wọn.
11 Ẹ̀gbé ni fún aṣebi! Ìparun wà lóríi wọnA ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.
12 Àwọn ọ̀dọ̀mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójúàwọn obìnrin ń jọba lé wọn lórí.Áà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti sìyín lọ́nà,wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.
13 Olúwa bọ sí ipo rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
14 Olúwa dojú ẹjọ́ kọàwọn alàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.“Ẹyin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15 Kín ni èro yín láti máa run àwọnènìyàn mi túútúútí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ?”ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.